ITAN KUKURU FUN ISEDALE ILU ÌJÈBÚ-JÈSÀ

Spread the love

ITAN KUKURU FUN ISEDALE ILU ÌJÈBÚ-JÈSÀ

NI EKUN IPINLE IWO OORUN NIGERIA.

LATI OWO
OBA ARÓJÒJOYÈ, II,  ÌJÈBÚ-JÈSÀ
1969

Oduduwa ni baba Oranmiyan, oranmiyan ni baba Agigiri I, Agigiri I ni  oba Ijebu Jesha, Oranmiyan yi ni o bi Eweka I ni Ado Binni. Obirin kan wa ni Ile - Ife ti oruko re nje Ijasin ni Ilode; Ijasin yi bi omobirin meta, arewa ni awon omo meteta yi gegebi iyaa won. Oruko awon omo meteta ni Omoremi Omutoto ati Pabiorunia. Oranmiyan omo Oduduwa fe eyi agba (Omoremi) se aya. Oduduwa ni baba Olofin, Olofin naa tun mu eyi atele omo iya yi ti oruko re nje Omutoto se aya (omo baba meji fe omo iya meji) Omoremi bi Agigiri fun Oranmiyan.

Ni osu keta ti Omoremi bimo ni Omutoto na bi Ajibogun fun Olofin. Nigbati o di osu keta ti Omutoto bimo ni Omutoto ku. Omoremi egbon Omutoto wa gbe Ajibogun omo Omutoto ti o si ntoju re pelu omo tire. Awon omo mejeji yi si jo ndagba po. Ajibogun yi ni Owa Ilesha, Agigiri ni Oba Ijebu-Jesha. Ajibogun ati egbon re Agigiri ni won jo lo te ile Ijesha do ti onikaluku si ni ipnle tire. Yara Igbo ni aala Owa Ilesha ati Oba Ijebu - Jesha. Ibuso meta ni Yara Igbo yi si Aafin Owa Ilesha, ibuso meta abo si ni si Aafin Oba Ijebu-Jesha. Lati Yara Igbo yi ni Oba Ijebu-Jesha ti ni ile titi ti o fi de aala Ijesha ati Ekiti. Yara igbo yi ti won gbe ni igba naa, jijin re to ese bata mewa (10 feet), ibu re to ese bata mefa (6 feet), gigun re to ibuso mejila (12 miles) eyi ti gbogbo oju si nri titi di oni oloni yi. Yara Igbo yi ni Ijoba fi se aala (Divisional Boundary) gege bi asa isedale.

Nigbati awon mejeji yi te ile Ijesha do tan ni won tun pada lo si Ile Ife lo ko awon eniyan wa. Won ko aadota (50) eniyan, Ajibogun mu ogbon (30), Agigiri naa mu ogun (20), onikaluku si mu awon eniyan tire lo si ile tire, eyi ni a fi npa lowe wipe “Ijebu ogun (20) Ilesha ogbon (30), ogun ko gbudo ra mogbon lara.”

Iboji Agigiri wa ni Aafin Ijebu-Jesha nibi ti Oba - Ijebu - Jesha ti nfi Owa Ilesha je Oye Owa titi di ono oloni yi

Awon ohun ini oba Ijebu-Jesha ti a le so die ninu won niyi:

ITIMOLE (CUSTODY) Iho ti won nso alaigboran si

UGBERE (PRISON YARD) Ibi ti nwon nko awon arufin ti won dajo ewon funni oko oba

Oba Ijebu-Ijesha nse idajo apaniyan. Igi Akoko ti Oba Ijebu-Ijesa ti npa awon arufin si wa nibe di isisiyi. Ogba Oba to 60 Acres.

Oba Ijebu Jesha ni awon oloye tire ti o nfi je oye ni Aafin tire. Awon Ijoye tire ti o nfi je ninu Aafin tire to Aadojo (150) oloye. Ninu awon oloye wonyi ni awon obirin Oloye naa wa pelu

Awon Oloye naa pin si ona mejo:

Iwarefa mefa

Egbe Are

Egbe Iwole

Egbe Legbewa

Egbe Esemure awon obirin

Olori omo merin

Awon Aworo mefa (Head of Idol worshipers) ati awon oloye re miran ni agbegbe Idamerin awon ijoye nse ipade awon oloye ni Aafin ni ojo marun marun, sugbon nisinyi, a ti so di ojo mejo-mejo (Mondays).

Oba Ijebu Jesha ni awon egbe Onisegun eyi ti Oloriawo Esigun je olori won (as medical officer and Nursing staff)

Oba Ijebu-Jesha ni awon egbe Babalawo (Seers) eyi ti Oluawo je olori won.

Oba Ijebu-Jesha ni awon Olode (Hunters) eyi ti Lumo-Ogun je Olori won, Tobalase si ni atele re.

Oba Ijebu-Jesha ni awon Gbena-Gbena eyi ti Oseunmu je olori won. Awon Gbenagbena yi ni won ngbe aworan (picture) awon ara atijo. Awon ni won si ngbe awo onje (wooding plates) fun Oba ni ododun ati gbogbo Ere (Sculpture) ti nwon nko si Aafin (Palace) pelu Odo (mortar) ti a fi ngun iyan pelu Oko Oju Odo (Canoe).

Oba  Ijebu-Jesha ni awon Alagbede (Goldsmith) eyi ti Olori won je Sajowa. Awon Alagbede ni won maa nro iso (Nail), eyi ti a npe ni Eserin, Ada (Cutlass), Oko (Hoe), Ibon (Gun), ati awon ohun ija gbogbo.

Oba Ijebu-Jesha ni awon Emese (Traditional Messangers) eyi ti olori won je Oloye Obalaye.

Oba Ijebu-Jesha ni awon elegbe Jagunjagun (Soldiers).

Oba Ijebu-Jesha ni o nfun awon eniyan re ni ile lati fi ko ile pelu lati fi da oko gege bi asa ibile.

Ijebu-Jesha ni asa ibile bi a se ntoro ati bi a se nfi omo fun okunrin se iyawo.

Ijebu-Jesha ni asa bi a se nfi eniyan je Oye.

Inu mi yio dun ti Ijoba ba le wa wo gbogbo awon nkan wonyi, won yio si ba bee. Asa eniyan pipa nikan ni Ijoba gba lowo Oba Ijebu-Jesha.

Ijoba Geesi ni o pa Ijebu-Jesha ati Ilesha po fun Ipade Asoju Oba Ilu Oyinbo ni 1886. Ijesha pelu Ekiti ni  Ijoba pa gbogbo wa po si oju kan naa ni Ilesha fun ipade.

Nigbati ajosepo Ijesha pelu Ekiti ko dogba nitori iwa iteloriba ti Ilesha nwu si won, ni won pada si aye won.

Oloye Adooko je omo omobirin Oba Ijebu-Jesha, idi eyi ni Oba Ijebu-Jesha se fi Oloye Adooko si aarin meji oko re ki o maa bojuto Ereko oun fu n oun. Adooko naa si wa ni oko naa (Idooko) titi di eni yi.

Ki ijoba Geesi to fi ipade apapo si Ilesha, Oba Ijebu-Jesha ni ni Oba Ijebu-Jesha nje, sugbon o di oran iwe akosile ni 1902 ni awon ara Ilesha so wipe ki won ko oruko naa ni Ogboni Ijebu-Jesha.

Owaoye ni Loja Imesi-Ile nje tele, lori iwe akosile yi ni awon ara Ilesha so wipe ki won maa pe ni Loja Imesi. Owamiran ni Loja Esa-Oke nje tele, lori iwe akosile yi ni awon ara Ilesha so wipe ki won maa pe ni Loja Esa-Oke. Iru iwa afipa teniloriba bayi ni won nhu si awon elegbe wa lati Ekiti, eyi yi lo mu ki won pada si Ilu won lai ba wa se po mo titi di eni. Major W. R. Reeve Tucker ni o wa ni asoju fun Ilesha fun Ijoba Geesi ni 1901 – 1902. Owa Ilesha ni Owa Ilesha nje nigbana, sugbon ni 1949 ti a gba Ominira (Divisional Council) kuro labe Ife ni won bere si npe Owa Ilesha ni Owa of  Ijesha Land.

ORO OGUN: Odun Ogun ni Oba Ijebu-Jesha nse ni ododun, eyi ti akoko re nbere ni Osu January. Oro Ogun yi ni a gbudo tete se ki awon agbe to lo maa san oko ajodun, ki asise ma baa si fun awon Agbe ni oko. Gbogbo Ilu ati awon ereko Oba Ijebu-Jesha ni won maa nda Isu (Yam), Oguro (Palm Wine), Epo (Palm Oil), Eran Igbe (Meat), Obi Abata (Kolanut) ati gbogbo ohun ti o ba to fun Isakole (Royalty) fun Oba Ijebu-Jesha ni ododun.

AWON OJO IRANTI PATAKI NI ILU IJEBU-JESHA (IMPORTANT DATES)

Oloogbe Alayeluwa Arojojoye I Oba Ijebu-Jesha je oye ni March 1910

A si Ile Olorun ijo C.M.S. ni 1914

Oloogbe Alayeluwa Arojojoye I ku ni January 14, 1929

Oloogbe Alayeluwa Amolese Oba Ijebu-Jesha je Oye ni June 22, 1929

A si Ile Ejo Ibile Ijebu-Jesha ni January 22, 1934

A si sile Egbogi Ijoba (Dispensary) Ibile Ijebu-Jesha ni 1938

Alayeluwa Oba Arojojoye II Oba Ijebu-Jesha je Oye ni March 8, 1947

A si Ile Eko Aarin (Modern School) ni January 1955

A si Ile Igbebi Alabiyamo (Maternity Centre) Ijebu-Jesha ni March 22, 1951

A si Ile Isere (Recreation Ground) ni 1955

Alayeluwa Arojojoye II, Oba Ilu Ijebu-Jesha fi Alayeluwa Biladu III, Owa Ilesha je oye Owa Ilesha ni Aafin Ijebu-Jesha gege bi asa ibile ni June 3, 1957

Oba Arojojoye II ti Ijebu-Jesha fi Owa Ilesha han gbogbo Ilesha ni iwaju Aafin Ilesha ni June 7, 1957, o si so ni oruko Fiwajoye.

Rev. D. A. Yoloye gba oye Alufa Ijo C. M. S, ni December 25, 1935

A si Ile Ifiweranse (Post Office) ni Ijebu Jesha ni January 16, 1941.

ITAN KUKURU NIPA OWA ILESHA ATI AAFIN OBA IJEBU-JESHA LATI ISEDALE

Owa Obokun Ilesha ni Akodi kan ti won ya soto fun ni Aafin Oba Ijebu-Jesha, ti a npe Akodi naa ni Ode Obokun titi di eni yi. Nitori pe ibe ni Owa Obokun ngbe nigba ti o ba wa si odo egbon re Oba Ijebu-Jesha. Nigba ti Owa Atakumosa fe lo si Ado Benin, o ko awon omo re (obirin marun) wa fun Oba Ijebu-Jesa, Atakumosa ko tii bi omokunrun rara nigbana. Oruko awon omomarun naa niyi:

Wayiero

Oriabe

Waji Akofon

Waye Oshun Ojara ati

Agunrogbo

Nitori awon omo marun yi ni Oba Ijebu-Jesha ati Owa Atakumosa se te Iwoye do, ti won si ko awon awon omo marun yi si ilu Iwoye naa, ti Oba Ijebu-Jesha si nse itoju won. Awon mararun yi ni Oba Ijebu-Jesha fi je Oye Owa Ilesha gege bi ojo ori won, ti won si ti ku tan ki Baba wo Atakumosa to ti Ado Benin de. Odu mejidinlaadorin (68 years) ni Atakumonsa se ni irin ajo naa ki o to pada si ori oye re.

Nigba ogun Jiriji ni 1879, Ode Obokun yi ni Owa Bepo maa nde si nigbati o ba wa si odo egbon re Oba Ijebu-Jesha

Gbogbo eni ti o ba fe je oye Owa Ilesha ni lati wa maa gbe ojo meta ni Aafin Ijebu-Jesha ki o to fi je oye Owa. Ti o ba yege ninu idanwo asa ibile ti Oba Ijebu-Jesha ba se fun, Akodi yi ni won maa ngbe, sugbon lati igba Owa Bepo ni won ti nwa nigba meta fun idanwo naa ki Oba Ijebu-Jesha to fi je oye Owa, ti o ba yege ninu idanwo naa, won kii sun nibe mo.

Ni 1928 ti awon ara ilu Ijebu-Jesha fe kan Aafin naa ni Paanu, Oba Owa Aromolaran fi ogorin (80) pako ranse si Oba Arojojoye I lati fi se Akodi naa.

Ni 1957 ti Owa Ogunmokun Biladu II fe je oye Owa, dipo ki o wa nigba meta, ojo kan ni a fi se idanwo pelu etutu naa fun, sugbon o pe pupo ni ojo naa, won de ni agogo kan osan, won si pada ni agogo mejo irole. Ode Obokun  yi naa ni ibi ti o fi se pataki ibujoko re ki o to lo si ibi etutu yoku. Nigba ti o ku ojo meta ki Oba Ogunmokun Biladu III wa je oye Owa ni Ijebu Jesha ni won ran alatunse ile (Contractor) kan wa siwaju lati lo tun Oke Obokun yi se, oruko Ogbeni naa ni Okelola.

Bi enikeni ba fe je Owa Ilesha, ti ko ba wa fun idanwo ati etutu ki Oba Ijebu jesha fi je oye, ko lee gbe odun meta lori oye naa gegebi asa isedale. Awon meji bee ti je oye Owa ni adamo ara won bee ri, ekini gbe odun kan abo, ekeji si gbe odun meji abo, lati igba naa ni won ko se bee mo.

“KI OLUWA JEKI EMI AWON OBA KI O GUN LATI LE MAA SE AKOSO RERE FUN AWON ENIYAN WON, ASE.”

Oba Ijebu-Jesha ti fi Owa Ilesha marun je ki Oloye Loro to de, eyini ni Owa OWALUSE, eni ti a ti owo re te Ilu Ilesha do. Oun ni Oloye Loro de ba nigbati o ti ilu re Ondo wa. Loro si ni eni ti o koko de wa ba Owa gbe ninu awon Ijoye yoku. A si ti fi Owa mokanla je ki Oloye Risawe Ilesha to de, oun ni eni ti o de se ikeji. Lehin won ni gbogbo awon Oloye yoku ti o wa ba Owa gbe Ilesha to nde.

OLOYE ODOLE: Odole je omo-odo ti a jijo ti Ile Ife wa, ti o si je iranse fun Owa ni gbogbo ibi-kibi ti won ba nlo titi di eni yi. Bi aye Owa ba sofo, Odole ni awon omo owa yio maa to lati le ran won lowo ki Oba Ijebu-Jesha le fi won je Oye. Ti won ba po, Oloye Odole a si mu bii marun ninu won wa fun Oba Ijebu-Jesha, won yio si se ayewo si eyi ti o ba dara. Eyi ti Oba Ijebu-Jesha ba ti mu ni won yio se idanwo fun ti yio si je Oye. Lati ojo naa ni o ti di baba fun awon ti o ku. Oloye Odole je oludamoran fifi eni je Owa Ilesha fu Oba Ijebu-Jesha. Bi enikeni ba sa to ijoye yoku ni Ilesha lo lati ran won lowo, Oloye naa yio mu eni naa lo si odo Oloye Odole fun iranlowo, Oloye Odole na yio si mu eni naa to Oba Ijebu-Jesha lo fun ase ti o ba ri pe o to bee.

ITAN NIPA IPINLE IJEBU-JESHA LATI AARO OJO PELU AWON ENIYAN RE NIYI

Okunrin kan wa ni ilu Ile-Ife ni igba iwase ti Olorun sokale wa si aye lati maa se ise agbe lati maa fun gbogbo awon eniyan ni ounje. Oruko okunrin naa ni Omiran (Ogbongbara). Sugbon nigbati okunrin alagbara (Omiran) yi wa dapo pelu obirin ti o si nbimo, Olorun tun mu ki ile lanu, ile si gbe mi, ko si jade mo titi. Nigbati  Owa Ajibogun pelu Oba Ijebu-Jesha Agigiri kuro ni Ile-Ife lati wa te Ile Ijesha do, ti onikaluku si pada si Ile-Ife lati lo ko awon eniyan wa si ori ile tire, Lumoko ati Ejemooje je omo Omiranwa ninu awon ti o ba Oba Agigiri wa lati Ile-Ife, won si mo pupo nipa isa agbe bi ti baba won. Oba Aigiri si fi won si ori ile tire ni ibikan ti a npe ni OMU, ti won si ndako nibe. Nibe naa ni Oba Ijebu-Jesha fi Ojumu pelu awon eniyan re ti a npe ni Agbega si ati Ajaaregbe pelu awon eniyan re ati Sajiku pelu awon eniyan re ti a npe ni Ijiku ti gbogbo won nse ise agbe nibe ati Aworo Okun ni igbo Aota pelu.

Oba Ijebu-Jesha da oja si Omu ti won npe oja naa ni Aleja Omu. Nigbati awon eniyan oniru nidi wa nba won na oja naa, ti enikeni ko si mo ibi ti won ti nwa. Nigbati iyonu awon Oniru nidi npo ju, ni gbogbo awon olugbe Omu yi fi ibe sile, ti Ejemu Oje at Lomoko fi lo tedo si Esa Egunre ti a npe ni Esa-Odo ni ojo eni. Lumoko yi fi omobirin Oba Ijebu-Jesha kan se aya, omobirin yi si bi omokunrin ka fun Lumoko. Igbati won mo omokunrin naa lori gege bi asa isedale, Omiran (baba Lumoko) ni o ya omokunrin naa. Nigbati omokunrin naa ni ojo lori ti o si di eni ti o to da gbe, o ko awon eniyan lowo lati odo baba re Lumoko lo tedo si egbe oke kan bi ibuso marun si baba re ti won si nse ise agbe nibe. Nibe ni won npe ni Esa oke titi di eni yi. Omokunrin alagbara yi wa je Oba won, Omiran ni oruko ti won npe, a si npe ni Oba Omiran (tabi Owa Omiran) Esa Oke titi di eni yi.

Ojumu pelu awon eniyan re ko pada wa si Ijebu-Jesha, Sajiku pelu awon eniyan re naa si ko pada wa si Ijebu-Jesha. Ajaaregbe ko awon eniyan tire sun si iwaju die, a mu Aworo Okun wa si Ilu Iwoye lehin igba ti a te Ilu Iwoye do fun awon omobirin Owa marun tan.

ILU EISUN: Ilu Eisun je ilu ti a ti owo Oba Ijebu-Jesha tedo ti o si ko awon eniyan re sibe, apa kan awon eniyan ti o kuro ni Omu naa ko lo sibe, ti Oba Ijebu-Jesha si fi eniyan re je olori fun won. Eni to Oba Ijebu-Jesha koko fi je olori fun won ni Akansa Egunmo. Omo ile Abowo-Owu ni Odo-Oja ni Ijebu-Jesha ni se, ti o si ti nda oko ni Omu tele. Eleisun keji nigbati Akansa Egunmo ku ni Amure (aburo Akansa Egunmo) joye; Igbati Amure ku ni a fi Eleisun keta je, eyi ti oruko re nje Akerele (omo Akansa Egunmo). Nigbati Akerele ku, ni a fi Adewumi ti o wa nibe yi je, omo Amure ni awon merin yi, awon ni won je Eleisun lati igba ti a ti te Eisun do.

Ilu Ibala, Idooko, Eisun ati awon ilu beebee ti o yi Ijebu-jesha ka je ilu ti a te do si ori ile Ijebu-Jesha. Eyi yi fihan pe Ijebu-Jesha duro gedegbe lati aaro pelu awon agbegbe re.

ERIN-IJESHA: Okunrin kan wa ni ilu Ijebu-Jesha ni aaro ojo ti oruko re nje Agbeleku ti o je akoni eniyan. Agbeleku yi fe omobirin Oba Ijebu-Jesha kan ti oruko re nje Orundodo se aya. Nigbati Oba Ijebu-Jesha ri wipe aye fe ha fun lati lo agbara ti o ni ni odo ohun, ni won ba so fun ki o rin siwaju die ki o lo tedo si, ni o ba mu iyawo re lo si ibi ti o to iwon ibuso mesan si Ijebu-Jesha. Nibe ni a npe ni Erin-Ijesha titi di eni yi. Omobirin Oba Ijebu-Jesha ti Agbeleku fi se aya yi (Orundodo) bi omokunrin kan ti won npe ni Olujobi (Owaluse). Agbeleku si je Oba si Erin. Lati ibe ni Owaluse ti wa je Owa Ilesha. Igbati Owalusu yi je Owa, gbogbo awon eniyan re (Erin) wa ba se eye, idi eyi ni awon obirin Erin wa maa npa ile nigbati Owa ba je. Omo Agbeleku yi ni Akinla nse ti o nje Oba Erin titi di eni yi.

ORUKO AWON ILU

Gbogbo awon ilu pataki-pataki ni agbegbe Ariwa Ijesha (Ijesha North) naa je awon ti won jijo je idipo kan soso ti Ile-Ife wa nigba isedale ti a o daruko die ninu won.

Ijebu-Ile ni Ijebu-Jesha nje tele ri, sugbon nigbati awon Oyo-Ibadan gbe ogun wa ti won fi Ijebu-Ile se ibudo, ere (abata) ni o yi gbogbo ilu naa ka, nigba naa ni won npe ni Ijebu-Ere. Eyi ni igba ogun Oyo-Ibadan ni 1873, nibe ni awon jagunjagun Oyo-Ibadan fi se ibudo gege bi olu ilu nigba naa.

Sugbon ni 1916 ti a bere si fi iwe ranse si okere ni ile ifi iwe ranse (Post Office) kekere wa ni Ilesha ni won bere si ni pe ilu naa ni Ijebu-Jesha. Awon omo ilu wa ti won je olaju ni won fi ori bari ti won so wipe Ilesha ni iwe won ni lati maa de si, nitori naa, Ijebu-Jesha ni won yio maa pe, Oba Alayeluwa Arojojoye I ni oba ti o wa lori ite nigba naa. Oba naa si gba imoran won nitori ati le maa tete ri iwe gba lati ile ifiweranse  Ilesha.

Oruko die ninu awon ilu yoku pataki pataki naa ni: Imesi-Ile; Otan-Ile; Otan-Koto ti a npe ni Otan-Ayegbaju ni ojo eni; Iresi; Igbajo; Efon-Alaye; Ido-Ajinare ati awon bee bee lo. Adugbo ni efon Alaye je ni Ijebu-Ile tele-tele ri, Ibi ti awon ara efon ti kuro ti a npe ni Igbomolefon ni Oba Arojojoye I fun ijo Anglican 1912 ti won ko ile Olorun si titi di eni yi. Ni odun naa ni Oba Alaye ni Efon wa ranse gbe Orisa won ti won ti fi sile lo lori ile naa, won si se etutu ki won to lo gbe Orisa naa si Efon.

Aala (Boundary): Oba Ijebu-Ile ni o ba Owa Ilesha se aala ni Yara Igbo ni Iwo-Oorun (West), Oba Ajero ti Ijero Ekiti ni Ariwa (North), Oba Orangun ti Ila ni Gusu (South), Oba Oshemowe ti Ondo ni Gusu (South). Gbogbo aala mererin yi je afojuri ti kii se itan nikan titi di eni yi. Sugbon nipa sise eto Ijoba Elekun je Ekun (Divisional Administration) lo mu iyapa die wa, sugbon kii se iyapa isedale rara.

Oruko die ninu awon Oba ti o je idile kan soso ti o ti je Oba sehin niyi:

Oba Agigiri I ti o ti Ile-Ife wa te Ilu Ijebu-Ile ati agbegbe re do bi Oba Agigiri II

Oba Agigiri II       bi

Oba Agigiri III      bi

Oba Arinyan        bi

Oba Edunde        bi

Oba Libayo         bi

Omobirin ti oruko re nje Folashade ti o lo fe ogbeni kan ni Ijeda   ti o bi omokunrin ti oruko re nje Ogbaruku fun Akoku

Oba Libayo tun   bi

Oba Igogodudu   bi

Oba Mubiabe      bi

Oba Orikayaki     bi

Oba Arojojoye I   bi

Oba Michael Kuye Arojojoye II

Nigba ti oba Orikayaki waja lo si orun, a ko ri omokunrin ti yio sun ori ite, nipa eyi ni won fi lo mu omo ti Folashade bi si Ijeda (Ogbaruku) ti o fi wa se adele fun odun meta.

Oba Ogbaruku bi Oba Obokundare Amolese

Oba Arojojoye II ti o je onigbagbo ati omowe kini ti o koko je oba ilu naa je Oba ni 1947. O lo si ile eko Ijo Mathew Mimo ni Ijebu-Jesha ni 1913 –1919, O sami (Baptist) ni 1915, O si gba igbowolelori Alufaa

(Bishop’s Confirmation) ni 1932 ninu Ijo naa.

IPETU-ILE

Okunrin kan wa ti won npe ni Elebedo ni Ipetu-Ile ti a npe ni Ipetu-Ijesha nisiyi ni a jijo ti Ile-Ife wa. Oun ni eni ti o tete lo joko si Ipetu na. Lehin ti Oba Agigiri ati Oranmiyan te Ilu naa do tan nigbati Oranmiyan ti Ado Benin pada.

IBOKUN

Okunrin kan wa ti a jijo ti Ile-Ife wa ti Oruko re nje Ohako. Oun ni eni ti o tete lo te Ibokun do siwaju nigbati Owa Obokun Ilesha wa ni Igbadao. Ohako yi ni awon Oyenla ati awon eniyan re ni won lo te Ibokun do lati owo Ba Agigiri Alase.

IDO AJINARE

Lati Ijebu-Ile ti a npe ni Ijebu-Jesha nisiyi ni awon osise agbe alagbara kan ti lo tedo si opin ile wa ti won si npe ibe ni Ido Ajinare ti won nda oko nibe titi ti won fi so di ilu, sugbon ile Olojudo yi ati apa kan awon eniyan re wa ni Ijebu-Jesha ti a si npe ile naa ile Olojudo ati apakan awon ti o lo si Ido yi tun pada wa ndako pelu wa lori ile kan naa ti a jijo ni ti ko si aala laari wa titi di eni yi.

“OTITO YIO SI SO E DI OMINIRA.”

Source:

OBA M. K. ARÓJÒJOYÈ, II