
ORÍKÌ ARÓJÒJOYÈ
Omo Arójòjoyè adélé tejiteji,
Ògbèrègèdè ó kólé ‘lè dorò,
Etí méta ò ye’rí,
Ènìyàn meta ò dúró ní méjì mejì,
Omo ìta gbangba ò se é kán kùn sÄ,
Omo okùnrin dúdú a b’ìjà kijan kijan,
Àjànbàtiàlà, ab’apá òsì bí apá òtún òle,Omo aládé pupa lórí esin,
Omo onílé owó,
Omo arúgbìnrín owó bó’dìdè,
Omo a jòfé là, omo aje igi emi sanra,
Omo ibi tí nwón n gbé òkú àgbò jòròjòrò wò,
Tí ojú á ro omo elòmÄràn kóró bí ùgbó,
Omo oníjèbú ègbòrò,
Omo awúre fàse banu,
Omo afisu mo’di,
Omo af’ògèdè di’gbà,
Oníjèbú oyè àyò,
Oníjèbú kojá omi,
Ó fòjá ògbómúdù nu’sè,
Omo oníbàtá àjó d’alé,
Ají sùn gégé,
Omo a rú gbogbo ude,
Síkùn odò agudu,
Omo a rí àléré ude,
K’ódò o mãlu sÄ,
Omo otá f’orí jo eja Àgbójà,
Omo won níjèbú,
Omo oníjèbú so agbogbo mó ìrókò,
Àgbà Ìwòyè so agbogbo mókun,
Ìnlé o.
Source:
Oba M.K. Arojojoye II Family