Omo Onijebu Egboro
Omo Egboroganluda
Omo Awure fase barun
Omo Asure fasenmenren tede
Omo Otaforijeja lagboja, ona ni mo ko Omo Onijebu
Omo Egburu ko yake; Egburu ya ginrin, ori bi eni bake, somiye
Omo OIuIe oo ekute yan an na
Omo Arugbinrn ao bodide
Omo Omoladan leku lelele oja
Omo Omoladan leku lelele Agboja, I an mu Moladan dagboja, agba Ijebu poju, rogo, won bu sekun, won pelemere, won ni ko nije ki a ri opo aye laje
Omoladan lapere Obinrin Oloja Abomu puru bi ile otoporo
Omo Afileke soge irun nita Ulode Ijasin fade Ufe
Omo Arikeragbe atusa ponmi lulese
Omo Onijebu Egboro
Oje a bati teni pipa, ti a teni pipa lagboja omoki seni a tun lomo se Ian ni K’agan la sun ni pakiti, k’eni bimo la sun lupa omi
Onijebu Omo Oyeayo
Omo Oloja o koja omi k’ofoja ogbomi nuse
Omo Oloja o koja omi tilu le koko
Omo Onijebu kole owo firoko yorirete
Omo Adipe fajoji jokekan
Omo adipe Oye f’enitirije
Omo Onijebu Ero-wo-tiru
Omo Onijebu ajoji lorira.
Omo Onijebu Ajoji ko wese
Ajoji o wese libe, Omo ko d’eni ebo.
Omo mora-mora to ra ugba eniyan lorijo
Omo Alagada kekeke igbi-oro Agada poyi ka ladodo o mo koro to nile ajobu
Omo asinrun lori enu, t’eru ba ku, aa tun sowo omirin
Omo Onile ibi an i gboku agbo jorojoro wo koju a ro omo oloririn koro bi ubo
Onijebu ya sule oni njokan, ogbogba okun gbe ko ba ya sule oni leremeji are a deni
Omo aralere ude k’edo eran ma1u si loke Atiba
Loye lo l’atiba; Onijebu lo Lagudu
Omo a rojigbogbo ude silekun odo Agudu l’Egboro
Akun Omo Ateniwijo
Omo Uroko to f’apakan mi sero, ko f’apakan mi so rubu ude
Omo Uroko ko gbojo odun, gbaja aso funfun l’Egboro
Omo Onijebu Egboro nibi Ogun gbedo de
Ibi Onibinuoni rosoo yun, ke rin riorio bo
Ibi OIniferanoni fudira1e, ke gbujigbura, kedomiye oni
Ijebu ogun, Ilesa ogbon k’ogun sa mara m’ogbon lara
Ian kegbon mogun, ian k’aburo mogbon ni ian se pin lodo Larao l’oke Atiba
Omo Olularahan rahan Owa danii pa ki Ijebu-Jesa ma mo
Omo Egboroganluda, Omo Ajobi Omo Ajobu
Omo Ajosa Omo Ajoda igbi ouro
Omo Ologbagbara-akun sorun l’oyin, l’Egboro Atiba
Omo Alade s’orisa loju kudukudu Ke jek’Ebora simi l’oke Atiba
Omo Arugbabowo lita ulode
Omo-afegelponmi terunalorun loke Atiba
Omo-afoofifogorun bi onigakaba, Ugbakeji Ela-Ururun-ungbe
Omo Oyeayo
Omo-arakatampo peiye lagbe-egan
Omo-Ogiriweranmole di pelebe lu
Omo Adade jinwinni f’urere-Okin yorire
Inleeo
Source:
50 Years of
Ijebu-Jesa Social Club (IJSC) in IJebu-Jesa History.
A 50th Anniversary Publication of IJSC
Edited By: Professor Akin ‘Femi Fajola & Dele Ogunyemi
First Published 2005